2 Ọba 6:24
2 Kings 6:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria.
2 Kings 6:24 in English
2 Kings 6:24 · Berean Standard Bible
Some time later, Ben-hadad king of Aram assembled his entire army and marched up to besiege Samaria.
Context
22“Má ṣe pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi síwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.” 23Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró. 24Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria. 25Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún. 26Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.