Native Bible

2 Kings 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dojúkọ wọ́n?” Ó béèrè. “Lọ́nà aginjù Edomu,” ó dáhùn.

2 Kings 3:8 in English

2 Kings 3:8 · Berean Standard Bible

Then he asked, “Which way shall we go up?” “By way of the Desert of Edom,” replied Joram.

Context

6Lásìkò ìgbà yìí ọba Jehoramu jáde kúrò ní Samaria ó sì yí gbogbo Israẹli ní ipò padà. 7Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Moabu jà?” Ọba Juda sì dáhùn pé, “Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ. Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.” 8“Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dojúkọ wọ́n?” Ó béèrè. “Lọ́nà aginjù Edomu,” ó dáhùn. 9Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli jáde lọ pẹ̀lú ọba Juda àti ọba Edomu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ-ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn. 10“Kí ni?” ọba Israẹli kígbe sókè. “Ṣé Olúwa pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.