2 Ọba 23:25
2 Kings 23:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose.
2 Kings 23:25 in English
2 Kings 23:25 · Berean Standard Bible
Neither before nor after Josiah was there any king like him, who turned to the LORD with all his heart and with all his soul and with all his strength, according to all the Law of Moses.
Context
23Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún tí ọba Josiah, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jerusalẹmu. 24Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa. 25Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose. 26Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú. 27Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, “Èmi yóò mú Juda kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Israẹli, èmi yóò sì kó Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.