2 Ọba 23:26
2 Kings 23:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú.
2 Kings 23:26 in English
2 Kings 23:26 · Berean Standard Bible
Nevertheless, the LORD did not turn away from the fury of His burning anger, which was kindled against Judah because of all that Manasseh had done to provoke Him to anger.
Context
24Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa. 25Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose. 26Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú. 27Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, “Èmi yóò mú Juda kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Israẹli, èmi yóò sì kó Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ” 28Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Josiah, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.