2 Ọba 21:18
2 Kings 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
2 Kings 21:18 in English
2 Kings 21:18 · Berean Standard Bible
And Manasseh rested with his fathers and was buried in his palace garden, the garden of Uzza. And his son Amon reigned in his place.
Context
16Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa. 17Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 18Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 19Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Orúkọ màmá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Meṣulemeti ọmọbìnrin Harusi: ó wá láti Jotba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. 20Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.