Native Bible

2 Kings 21:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda?

2 Kings 21:17 in English

2 Kings 21:17 · Berean Standard Bible

As for the rest of the acts of Manasseh, along with all his accomplishments and the sin that he committed, are they not written in the Book of the Chronicles of the Kings of Judah?

Context

15nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.” 16Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa. 17Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 18Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 19Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Orúkọ màmá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Meṣulemeti ọmọbìnrin Harusi: ó wá láti Jotba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.