2 Ọba 21:15
2 Kings 21:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.”
2 Kings 21:15 in English
2 Kings 21:15 · Berean Standard Bible
because they have done evil in My sight and have provoked Me to anger from the day their fathers came out of Egypt until this day.’”
Context
13Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀n kan tí a lò lórí Jerusalẹmu àti lórí Samaria àti òjé ìdiwọ̀n ti a lò lórí ilé Ahabu. Èmi yóò sì nu Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù tí o ń nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò. 14Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, 15nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.” 16Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa. 17Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.