Native Bible

2 Kings 20:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò.

2 Kings 20:3 in English

2 Kings 20:3 · Berean Standard Bible

“Please, O LORD, remember how I have walked before You faithfully and with wholehearted devotion; I have done what was good in Your sight.” And Hezekiah wept bitterly.

Context

1Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.” 2Hesekiah yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé, 3“Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò. 4Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: 5“Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.