Native Bible

2 Kings 20:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

2 Kings 20:5 in English

2 Kings 20:5 · Berean Standard Bible

“Go back and tell Hezekiah the leader of My people that this is what the LORD, the God of your father David, says: ‘I have heard your prayer; I have seen your tears. I will surely heal you. On the third day from now you will go up to the house of the LORD.

Context

3“Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò. 4Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: 5“Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 6Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ” 7Nígbà náà ni Isaiah wí pé, “Mú odidi ọ̀pọ̀tọ́.” Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fi lé oówo náà, ara rẹ̀ sì yá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.