2 Ọba 20:13
2 Kings 20:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hesekiah gba ìránṣẹ́ náà ó sì fihàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò sì fihàn wọ́n.
2 Kings 20:13 in English
2 Kings 20:13 · Berean Standard Bible
And Hezekiah received the envoys and showed them all that was in his treasure house—the silver, the gold, the spices, and the precious oil, as well as his armory—all that was found in his storehouses. There was nothing in his palace or in all his dominion that Hezekiah did not show them.
Context
11Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi. 12Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli ránṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Hesekiah nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Hesekiah. 13Hesekiah gba ìránṣẹ́ náà ó sì fihàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò sì fihàn wọ́n. 14Nígbà náà Isaiah wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?”
“Láti ìlú jíjìn réré,” Hesekiah dáhùn. “Wọ́n wá láti Babeli.” 15Wòlíì náà béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ?”
“Wọ́n rí gbogbo nǹkan ní ààfin mi,” Hesekiah wí pé. “Kò sí nǹkan kan lára àwọn ìṣúra tí èmi kò fihàn wọ́n.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.