Native Bible

2 Kings 20:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà Isaiah wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?” “Láti ìlú jíjìn réré,” Hesekiah dáhùn. “Wọ́n wá láti Babeli.”

2 Kings 20:14 in English

2 Kings 20:14 · Berean Standard Bible

Then the prophet Isaiah went to King Hezekiah and asked, “Where did those men come from, and what did they say to you?” “They came from a distant land,” Hezekiah replied, “from Babylon.”

Context

12Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli ránṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Hesekiah nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Hesekiah. 13Hesekiah gba ìránṣẹ́ náà ó sì fihàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò sì fihàn wọ́n. 14Nígbà náà Isaiah wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?” “Láti ìlú jíjìn réré,” Hesekiah dáhùn. “Wọ́n wá láti Babeli.” 15Wòlíì náà béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ?” “Wọ́n rí gbogbo nǹkan ní ààfin mi,” Hesekiah wí pé. “Kò sí nǹkan kan lára àwọn ìṣúra tí èmi kò fihàn wọ́n.” 16Nígbà náà Isaiah wí fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.