2 Ọba 2:19
2 Kings 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé, “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.”
2 Kings 2:19 in English
2 Kings 2:19 · Berean Standard Bible
Then the men of the city said to Elisha, “Please note, our lord, that the city’s location is good, as you can see. But the water is bad and the land is unfruitful.”
Context
17Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́ títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò rí i. 18Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?” 19Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé, “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.” 20Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un. 21Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.