2 Ọba 2:1
2 Kings 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Olúwa ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali.
2 Kings 2:1 in English
2 Kings 2:1 · Berean Standard Bible
Shortly before the LORD took Elijah up to heaven in a whirlwind, Elijah and Elisha were on their way from Gilgal,
Context
1Nígbà tí Olúwa ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. 2Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Beteli.”
Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli. 3Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”
“Bẹ́ẹ̀ ni, èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.