Native Bible

2 Kings 18:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í.

2 Kings 18:9 in English

2 Kings 18:9 · Berean Standard Bible

In the fourth year of Hezekiah’s reign, which was the seventh year of the reign of Hoshea son of Elah over Israel, Shalmaneser king of Assyria marched against Samaria and besieged it.

Context

7Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín. 8Láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Filistini run, àti títí dé Gasa àti agbègbè rẹ̀. 9Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í. 10Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Asiria gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Samaria ní ọdún kẹfà Hesekiah tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsànán Hosea ọba Israẹli. 11Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.