2 Ọba 18:7
2 Kings 18:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín.
2 Kings 18:7 in English
2 Kings 18:7 · Berean Standard Bible
And the LORD was with Hezekiah, and he prospered wherever he went. He rebelled against the king of Assyria and refused to serve him.
Context
5Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀. 6Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose. 7Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín. 8Láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Filistini run, àti títí dé Gasa àti agbègbè rẹ̀. 9Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.