Native Bible

2 Kings 18:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.

2 Kings 18:5 in English

2 Kings 18:5 · Berean Standard Bible

Hezekiah trusted in the LORD, the God of Israel. No king of Judah was like him, either before him or after him.

Context

3Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe. 4Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ àwọn ère òkúta, ó sì gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀, ó sì fọ́ ejò idẹ tí Mose ti ṣe náà túútúú, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Nehuṣitani.) 5Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀. 6Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose. 7Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.