2 Ọba 17:31
2 Kings 17:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti àwọn ará Afa ṣe Nibhasi àti Tartaki, àti àwọn ará Sefarfaimi sun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adrameleki àti Anameleki, àwọn òrìṣà Sefarfaimi.
2 Kings 17:31 in English
2 Kings 17:31 · Berean Standard Bible
the Avvites made Nibhaz and Tartak, and the Sepharvites burned their children in the fire to Adrammelech and Anammelech the gods of the Sepharvaim.
Context
29Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Samaria ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima; 31àti àwọn ará Afa ṣe Nibhasi àti Tartaki, àti àwọn ará Sefarfaimi sun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adrameleki àti Anameleki, àwọn òrìṣà Sefarfaimi. 32Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga. 33Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀-èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.