2 Ọba 17:32
2 Kings 17:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga.
2 Kings 17:32 in English
2 Kings 17:32 · Berean Standard Bible
So the new residents worshiped the LORD, but they also appointed for themselves priests of all sorts to serve in the shrines of the high places.
Context
30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima; 31àti àwọn ará Afa ṣe Nibhasi àti Tartaki, àti àwọn ará Sefarfaimi sun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adrameleki àti Anameleki, àwọn òrìṣà Sefarfaimi. 32Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga. 33Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀-èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá. 34Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jakọbu, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.