2 Ọba 15:30
2 Kings 15:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah.
2 Kings 15:30 in English
2 Kings 15:30 · Berean Standard Bible
Then Hoshea son of Elah led a conspiracy against Pekah son of Remaliah. In the twentieth year of Jotham son of Uzziah, Hoshea attacked Pekah, killed him, and reigned in his place.
Context
28Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá. 29Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. 30Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah. 31Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 32Ní ọdún keje Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli, Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.