Native Bible

2 Kings 15:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria.

2 Kings 15:29 in English

2 Kings 15:29 · Berean Standard Bible

In the days of Pekah king of Israel, Tiglath-pileser king of Assyria came and captured Ijon, Abel-beth-maacah, Janoah, Kedesh, Hazor, Gilead, and Galilee, including all the land of Naphtali, and he took the people as captives to Assyria.

Context

27Ní ọdún kejìléláàádọ́ta Asariah ọba Juda, Peka ọmọ Remaliah di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ogún ọdún. 28Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá. 29Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. 30Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah. 31Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.