Native Bible

2 Kings 15:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

2 Kings 15:20 in English

2 Kings 15:20 · Berean Standard Bible

Menahem exacted this money from each of the wealthy men of Israel—fifty shekels of silver * from each man—to give to the king of Assyria. So the king of Assyria withdrew and did not remain in the land.

Context

18Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 19Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba. 20Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́. 21Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli? 22Menahemu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pekahiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.