2 Ọba 15:21
2 Kings 15:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli?
2 Kings 15:21 in English
2 Kings 15:21 · Berean Standard Bible
As for the rest of the acts of Menahem, along with all his accomplishments, are they not written in the Book of the Chronicles of the Kings of Israel?
Context
19Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba. 20Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́. 21Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli? 22Menahemu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pekahiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 23Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.