Native Bible

2 Kings 15:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá.

2 Kings 15:17 in English

2 Kings 15:17 · Berean Standard Bible

In the thirty-ninth year of Azariah’s reign over Judah, Menahem son of Gadi became king of Israel, and he reigned in Samaria ten years.

Context

15Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 16Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún. 17Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá. 18Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 19Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.