Native Bible

2 Kings 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

2 Kings 15:16 in English

2 Kings 15:16 · Berean Standard Bible

At that time Menahem, starting from Tirzah, attacked Tiphsah and everyone in its vicinity, because they would not open their gates. So he attacked Tiphsah and ripped open all the pregnant women.

Context

14Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 15Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 16Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún. 17Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá. 18Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.