Native Bible

2 Kings 15:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

2 Kings 15:15 in English

2 Kings 15:15 · Berean Standard Bible

As for the rest of the acts of Shallum, along with the conspiracy he led, they are indeed written in the Book of the Chronicles of the Kings of Israel.

Context

13Ṣallumu ọmọ Jabesi di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ussiah ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún oṣù kan. 14Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 15Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 16Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún. 17Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.