2 Ọba 11:17
2 Kings 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú.
2 Kings 11:17 in English
2 Kings 11:17 · Berean Standard Bible
Then Jehoiada made a covenant between the LORD and the king and the people that they would be the LORD’s people. He also made a covenant between the king and the people.
Context
15Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.” 16Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á. 17Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú. 18Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.
Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 19Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú ààyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.