2 Ọba 11:16
2 Kings 11:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á.
2 Kings 11:16 in English
2 Kings 11:16 · Berean Standard Bible
So they seized Athaliah as she reached the horses’ entrance to the palace grounds, and there she was put to death.
Context
14Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn balógun àti àwọn afùnpè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀, wọ́n sì ń fun ìpè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataliah fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!” 15Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.” 16Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á. 17Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú. 18Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.
Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.