2 Kọrinti 7:6
2 Corinthians 7:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé,
2 Corinthians 7:6 in English
2 Corinthians 7:6 · Berean Standard Bible
But God, who comforts the downcast, comforted us by the arrival of Titus,
Context
4Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa. 5Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. 6Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé, 7kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀. 8Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.