Native Bible

2 Corinthians 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.

2 Corinthians 7:4 in English

2 Corinthians 7:4 · Berean Standard Bible

Great is my confidence in you; great is my pride in you; I am filled with encouragement; in all our troubles my joy overflows.

Context

2Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. 3Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. 4Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa. 5Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. 6Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.