2 Kọrinti 11:25
2 Corinthians 11:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.
2 Corinthians 11:25 in English
2 Corinthians 11:25 · Berean Standard Bible
Three times I was beaten with rods, once I was stoned, three times I was shipwrecked. I spent a night and a day in the open sea.
Context
23Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26Ní ìrìnàjò nígbàkígbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkígbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkígbà, nínú òtútù àti ìhòhò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.