Native Bible

2 Corinthians 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù.

2 Corinthians 11:24 in English

2 Corinthians 11:24 · Berean Standard Bible

Five times I received from the Jews the forty lashes minus one.

Context

22Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26Ní ìrìnàjò nígbàkígbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.