Native Bible

2 Corinthians 11:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀.

2 Corinthians 11:23 in English

2 Corinthians 11:23 · Berean Standard Bible

Are they servants of Christ? I am speaking like I am out of my mind, but I am so much more: in harder labor, in more imprisonments, in worse beatings, in frequent danger of death.

Context

21Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera! Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.