2 Kronika 6:35
2 Chronicles 6:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.
2 Chronicles 6:35 in English
2 Chronicles 6:35 · Berean Standard Bible
then may You hear from heaven their prayer and their plea, and may You uphold their cause.
Context
33Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́. 34“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. 35Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró. 36“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, 37ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.