Native Bible

2 Chronicles 6:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí,

2 Chronicles 6:36 in English

2 Chronicles 6:36 · Berean Standard Bible

When they sin against You—for there is no one who does not sin—and You become angry with them and deliver them to an enemy who takes them as captives to a land far or near,

Context

34“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé Olúwa tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. 35Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró. 36“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, 37ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’; 38tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.