Native Bible

2 Chronicles 6:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

2 Chronicles 6:26 in English

2 Chronicles 6:26 · Berean Standard Bible

When the skies are shut and there is no rain because Your people have sinned against You, and they pray toward this place and confess Your name, and they turn from their sins because You have afflicted them,

Context

24“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí, 25nígbà náà, ni kí o gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn. 26“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 27nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní. 28“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.