Native Bible

2 Chronicles 6:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí,

2 Chronicles 6:24 in English

2 Chronicles 6:24 · Berean Standard Bible

When Your people Israel are defeated before an enemy because they have sinned against You, and they return to You and confess Your name, praying and pleading before You in this temple,

Context

22“Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, 23nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. 24“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí, 25nígbà náà, ni kí o gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn. 26“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.