Native Bible

2 Chronicles 6:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí,

2 Chronicles 6:22 in English

2 Chronicles 6:22 · Berean Standard Bible

When a man sins against his neighbor and is required to take an oath, and he comes to take an oath before Your altar in this temple,

Context

20Kí ojú rẹ kí ó lè ṣí sí ilé Olúwa ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí. 21Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjì. 22“Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, 23nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. 24“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé Olúwa yìí,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.