2 Kronika 6:27
2 Chronicles 6:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní.
2 Chronicles 6:27 in English
2 Chronicles 6:27 · Berean Standard Bible
then may You hear from heaven and forgive the sin of Your servants, Your people Israel, so that You may teach them the good way in which they should walk. May You send rain on the land that You gave Your people as an inheritance.
Context
25nígbà náà, ni kí o gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn. 26“Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 27nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní. 28“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá. 29Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé Olúwa yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.