2 Kronika 35:6
2 Chronicles 35:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.”
2 Chronicles 35:6 in English
2 Chronicles 35:6 · Berean Standard Bible
Slaughter the Passover lambs, consecrate yourselves, and make preparations for your fellow countrymen to carry out the word of the LORD given by * Moses.”
Context
4Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dafidi ọba Israẹli àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Solomoni. 5“Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Lefi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀. 6Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.” 7Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba. 8Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹran ọ̀sìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.