2 Kronika 35:8
2 Chronicles 35:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹran ọ̀sìn.
2 Chronicles 35:8 in English
2 Chronicles 35:8 · Berean Standard Bible
His officials also contributed willingly to the people and priests and Levites. Hilkiah, Zechariah, and Jehiel, the administrators of the house of God, gave the priests 2,600 Passover offerings and 300 bulls.
Context
6Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.” 7Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba. 8Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹran ọ̀sìn. 9Àti pẹ̀lú Konaniah àti pẹ̀lú Ṣemaiah àti Netaneli, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabiah, Jeieli àti Josabadi olórí àwọn ọmọ Lefi, ó sì pèsè ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹbọ ìrékọjá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Lefi. 10Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.