2 Kronika 35:5
2 Chronicles 35:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Lefi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀.
2 Chronicles 35:5 in English
2 Chronicles 35:5 · Berean Standard Bible
Moreover, stand in the Holy Place by the divisions of the families of your kinsmen the lay people, and by the divisions of the families of the Levites.
Context
3Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. 4Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dafidi ọba Israẹli àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Solomoni. 5“Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Lefi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀. 6Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.” 7Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.