2 Kronika 34:22
2 Chronicles 34:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì.
2 Chronicles 34:22 in English
2 Chronicles 34:22 · Berean Standard Bible
So Hilkiah and those the king had designated went and spoke to Huldah * the prophetess, the wife of Shallum son of Tokhath,* the son of Hasrah,* the keeper of the wardrobe. She lived in Jerusalem, in the Second District.*
Context
20Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 21“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.” 22Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì. 23Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, 24‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.