2 Kronika 34:21
2 Chronicles 34:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
2 Chronicles 34:21 in English
2 Chronicles 34:21 · Berean Standard Bible
“Go and inquire of the LORD for me and for those remaining in Israel and Judah concerning the words in the book that has been found. For great is the wrath of the LORD that has been poured out on us because our fathers have not kept the word of the LORD by doing all that is written in this book.”
Context
19Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. 20Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 21“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.” 22Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì. 23Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.