Native Bible

2 Chronicles 34:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.”

2 Chronicles 34:24 in English

2 Chronicles 34:24 · Berean Standard Bible

that this is what the LORD says: I am about to bring calamity on this place and on its people, according to all the curses written in the book that has been read in the presence of the king of Judah,

Context

22Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì. 23Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, 24‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.” 25Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’ 26Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.