2 Kronika 32:20
2 Chronicles 32:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Hesekiah àti wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sọkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí.
2 Chronicles 32:20 in English
2 Chronicles 32:20 · Berean Standard Bible
In response, King Hezekiah and the prophet Isaiah son of Amoz cried out to heaven in prayer,
Context
18Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Heberu sí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ fún wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà. 19Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Jerusalẹmu bí wọ́n ti ṣe nípa àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn mìíràn ti àgbáyé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn. 20Ọba Hesekiah àti wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sọkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí. 21Olúwa sì ran angẹli tí ó pa gbogbo àwọn ọmọ-ogun àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Asiria run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà. 22Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Hesekiah àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ Sennakeribu ọba Asiria àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.