Native Bible

2 Chronicles 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.

2 Chronicles 3:9 in English

2 Chronicles 3:9 · Berean Standard Bible

The weight of the nails was fifty shekels of gold.* He also overlaid the upper area with gold.

Context

7Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri. 8Ó kọ́ Ibi Mímọ́ Jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára. 9Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà. 10Ní Ibi Mímọ́ Jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà. 11Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.