2 Kronika 29:33
2 Chronicles 29:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ohun ìyàsímímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600) màlúù, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn.
2 Chronicles 29:33 in English
2 Chronicles 29:33 · Berean Standard Bible
And the consecrated offerings were six hundred bulls and three thousand sheep.
Context
31Nígbà náà ni Hesekiah dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún Olúwa, ẹ súnmọ́ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá sínú ilé Olúwa. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá. 32Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùn-ún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn, gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ sísun sí Olúwa. 33Àwọn ohun ìyàsímímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600) màlúù, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. 34Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣẹ́ náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòtítọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́. 35Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun.
Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ilé Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.