Native Bible

2 Chronicles 29:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣẹ́ náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòtítọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́.

2 Chronicles 29:34 in English

2 Chronicles 29:34 · Berean Standard Bible

However, since there were not enough priests to skin all the burnt offerings, their Levite brothers helped them until the work was finished and until the priests had been consecrated. For the Levites had been more diligent in consecrating themselves than the priests had been.

Context

32Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùn-ún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn, gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ sísun sí Olúwa. 33Àwọn ohun ìyàsímímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600) màlúù, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. 34Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣẹ́ náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòtítọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́. 35Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ilé Olúwa. 36Hesekiah sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.