Native Bible

2 Chronicles 29:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli.

2 Chronicles 29:24 in English

2 Chronicles 29:24 · Berean Standard Bible

And the priests slaughtered the goats and put their blood on the altar for a sin offering, to make atonement for all Israel, because the king had ordered the burnt offering and the sin offering for all Israel.

Context

22Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ. 23Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli. 25Ó sì mú àwọn Lefi dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Gadi aríran ọba àti Natani wòlíì. Èyí ni a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀. 26Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ìpè wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.