Native Bible

2 Chronicles 29:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì mú àwọn Lefi dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Gadi aríran ọba àti Natani wòlíì. Èyí ni a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀.

2 Chronicles 29:25 in English

2 Chronicles 29:25 · Berean Standard Bible

Hezekiah stationed the Levites in the house of the LORD with cymbals, harps, and lyres according to the command of David, of Gad the king’s seer, and of Nathan the prophet. For the command had come from the LORD through His prophets.

Context

23Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli. 25Ó sì mú àwọn Lefi dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Gadi aríran ọba àti Natani wòlíì. Èyí ni a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀. 26Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ìpè wọn. 27Hesekiah sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi ọba Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.